Native Bible

Hebrews 6:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwa ní ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní tiyín, àti ohun tí ó fi ara mọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀.

Hebrews 6:9 in English

Hebrews 6:9 · Berean Standard Bible

Even though we speak like this, beloved, we are convinced of better things in your case—things that accompany salvation.

Context

7Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hu ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run. 8Ṣùgbọ́n bí ó ba ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò di kíkọ̀sílẹ̀, kò si jìnnà sí fífi gégùn ún, òpin èyí tí yóò wà fún ìjóná. 9Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwa ní ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní tiyín, àti ohun tí ó fi ara mọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀. 10Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe. 11Àwa sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsimi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.