Heberu 12:16
Hebrews 12:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí o má bá à si àgbèrè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Esau, ẹni tí o tìtorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀.
Hebrews 12:16 in English
Hebrews 12:16 · Berean Standard Bible
See to it that no one is sexually immoral, or is godless like Esau, who for a single meal sold his birthright.
Context
14Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa. 15Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà Oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí gbòǹgbò ìkorò kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́. 16Kí o má bá à si àgbèrè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Esau, ẹni tí o tìtorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀. 17Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ́yìn náà, nígbà tí ó fẹ́ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri ààyè ìrònúpìwàdà, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wa a gidigidi. 18Nítorí ẹ̀yin kò wá òkè tí a lè fi ọwọ́ kàn, àti ti iná ti ń jó, àti ti ìṣúdudu àti òkùnkùn, àti ìjì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.