Native Bible

Hebrews 11:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nípa ìgbàgbọ́ ni o kọ Ejibiti sílẹ̀ láìbẹ̀rù ìbínú ọba: nítorí tí o dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó n ri ẹni àìrí.

Hebrews 11:27 in English

Hebrews 11:27 · Berean Standard Bible

By faith Moses left Egypt, not fearing the king’s anger; he persevered because he saw Him who is invisible.

Context

25o kúkú yàn láti máa ba àwọn ènìyàn Ọlọ́run jìyà, ju jíjẹ fàájì ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀. 26Ó ka ẹ̀gàn Kristi si ọrọ̀ tí ó pọ̀jù àwọn ìṣúra Ejibiti lọ, nítorí tí ó ń wo èrè náà. 27Nípa ìgbàgbọ́ ni o kọ Ejibiti sílẹ̀ láìbẹ̀rù ìbínú ọba: nítorí tí o dúró ṣinṣin bí ẹni tí ó n ri ẹni àìrí. 28Nípa ìgbàgbọ́ ni ó da àsè ìrékọjá sílẹ̀, àti ìbùwọ́n ẹ̀jẹ̀, kí ẹni tí ń pa àwọn àkọ́bí ọmọ má bá a fi ọwọ́ kan wọn. 29Nípa ìgbàgbọ́ ni wọn la òkun pupa kọjá bi ẹni pé ni ìyàngbẹ ilẹ̀ ni: ti àwọn ara Ejibiti dánwò, tí wọ́n sì ri.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.