Heberu 11:13
Hebrews 11:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ó kú nínú ìgbàgbọ́, láìrí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, tí wọ́n sì gbá wọn mú, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ pé àlejò àti àjèjì ni àwọn lórí ilẹ̀ ayé.
Hebrews 11:13 in English
Hebrews 11:13 · Berean Standard Bible
All these people died in faith, without having received the things they were promised. However, they saw them and welcomed them from afar. And they acknowledged that they were strangers and exiles on the earth.
Context
11Nípa ìgbàgbọ́ ni Sara tìkára rẹ̀ pẹ̀lú fi gba agbára láti lóyún, nígbà tí ó kọjá ìgbà rẹ̀, nítorí tí o ka ẹni tí o ṣe ìlérí sí olóòótọ́. 12Nítorí náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ṣe ti ara ọkùnrin kan jáde, àní ara ẹni tí o dàbí òkú, ọmọ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run lọ́pọ̀lọ́pọ̀, àti bí iyanrìn etí Òkun láìníye. 13Gbogbo àwọn wọ̀nyí ni ó kú nínú ìgbàgbọ́, láìrí àwọn ìlérí náà gbà, ṣùgbọ́n tí wọn rí wọn ni òkèrè réré, tí wọ́n sì gbá wọn mú, tí wọ́n sì jẹ́wọ́ pé àlejò àti àjèjì ni àwọn lórí ilẹ̀ ayé. 14Nítorí pé àwọn tí o ń sọ irú ohun bẹ́ẹ̀ fihàn gbangba pé, wọn ń ṣe àfẹ́rí ìlú kan tí i ṣe tiwọn. 15Àti nítòótọ́, ìbá ṣe pé wọ́n fi ìlú tiwọn tí jáde wá sí ọkàn, wọn ìbá ti rí ààyè padà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.