Heberu 10:1
Hebrews 10:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí tí òfin jẹ́ òjìji àwọn ohun rere ti ń bọ̀ tí kì í ṣe àwòrán tòótọ́ fún àwọn òtítọ́ náà, wọn kò lè fi ẹbọ kan náà tí wọn ń rú nígbà gbogbo lọ́dọọdún mu àwọn tí ń wá jọ́sìn di pípé.
Hebrews 10:1 in English
Hebrews 10:1 · Berean Standard Bible
For the law is only a shadow of the good things to come, not the realities themselves. It can never, by the same sacrifices offered year after year, make perfect those who draw near to worship.
Context
1Nítorí tí òfin jẹ́ òjìji àwọn ohun rere ti ń bọ̀ tí kì í ṣe àwòrán tòótọ́ fún àwọn òtítọ́ náà, wọn kò lè fi ẹbọ kan náà tí wọn ń rú nígbà gbogbo lọ́dọọdún mu àwọn tí ń wá jọ́sìn di pípé. 2Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, a kì ìbá tí dẹ́kun àti máa rú wọn, nítorí àwọn ti ń sìn ki ìbá tí ní ìmọ̀ ẹ̀ṣẹ̀, nígbà tí a bá ti wẹ̀ wọ́n mọ́ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. 3Ṣùgbọ́n nínú ẹbọ wọ̀nyí ni a ń ṣe ìrántí ẹ̀ṣẹ̀ lọ́dọọdún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.