Native Bible

Hebrews 1:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró. Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè.

Hebrews 1:3 in English

Hebrews 1:3 · Berean Standard Bible

The Son is the radiance of God’s glory and the exact representation of His nature, upholding all things by His powerful word. After He had provided purification for sins, He sat down at the right hand of the Majesty on high.

Context

1Ní ìgbà àtijọ́, Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá wa sọ̀rọ̀ láti ẹnu àwọn wòlíì ní ọ̀pọ̀ ìgbà àti ní onírúurú ọ̀nà, 2ṣùgbọ́n ní ìgbà ìkẹyìn yìí Ọlọ́run ń bá wa sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tí ó fi ṣe ajogún ohun gbogbo, nípasẹ̀ ẹni tí ó dá gbogbo ayé yìí àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀. 3Ọmọ tí í ṣe ìtànṣán ògo Ọlọ́run àti àwòrán òun tìkára rẹ̀, tí ó sì ń fi ọ̀rọ̀ agbára rẹ̀ mú ohun gbogbo dúró. Lẹ́yìn tí ó ti ṣe ìwẹ̀nù ẹ̀ṣẹ̀ wa tan, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọláńlá ní òkè. 4Nítorí náà, ó sì ti fi bẹ́ẹ̀ di ẹni tí ó ga ní ipò ju angẹli lọ, bí ó ti jogún orúkọ èyí tí ó tayọ̀ tiwọn. 5Nítorí kò sí ọ̀kan nínú àwọn angẹli tí Ọlọ́run fi ìgbà kan sọ fún pé: “Ìwọ ni ọmọ mi; lónìí ni mo bí ọ”? Àti pẹ̀lú pé, “Èmi yóò jẹ́ baba fún un, Òun yóò sì jẹ́ ọmọ mi”?

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.