Native Bible

Haggai 2:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé:

Haggai 2:11 in English

Haggai 2:11 · Berean Standard Bible

“This is what the LORD of Hosts says: ‘Ask the priests for a ruling.

Context

9‘Ògo ìkẹyìn ilé yìí yóò pọ̀ ju ti ìṣáájú lọ,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Àti ní ìhín yìí ni Èmi ó sì fi àlàáfíà fún ni,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.” 10Ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹsànán ní ọdún kejì Dariusi, ni ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Hagai wá pé, 11“Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Béèrè lọ́wọ́ àwọn àlùfáà ohun tí òfin wí pé: 12Bí ẹnìkan bá gbé ẹran mímọ́ ní ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, tí ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀ kan àkàrà tàbí ọbẹ̀, wáìnì, òróró tàbí oúnjẹ mìíràn, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ mímọ́ bí?’ ” Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́.” 13Nígbà náà ni Hagai wí pé, “Bí ẹnìkan tí ó jẹ́ aláìmọ́ nípa fífi ara kan òkú bá fi ara kan ọ̀kan lára nǹkan wọ̀nyí, ǹjẹ́ yóò ha jẹ́ aláìmọ́?” Àwọn àlùfáà sì dáhùn wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, yóò jẹ́ aláìmọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.