Native Bible

Haggai 1:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nísìnsinyìí, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.

Haggai 1:5 in English

Haggai 1:5 · Berean Standard Bible

Now this is what the LORD of Hosts says: “Consider carefully your ways.

Context

3Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa wá láti ọ̀dọ̀ wòlíì Hagai wí pé, 4“Ǹjẹ́ àkókò ni fún ẹ̀yin fúnra yín láti máa gbé ní ilé tí a ṣe ní ọ̀ṣọ́ nígbà tí ilé yìí wà ni ahoro?” 5Nísìnsinyìí, èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín. 6Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀. Ẹ̀yin jẹun, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; ẹyin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.” 7Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.