Hagai 1:14
Haggai 1:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, Olúwa ru ẹ̀mí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli sókè, baálẹ̀ Juda àti ẹ̀mí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù. Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn,
Haggai 1:14 in English
Haggai 1:14 · Berean Standard Bible
So the LORD stirred the spirit of Zerubbabel son of Shealtiel, governor of Judah, and the spirit of Joshua son of Jehozadak, the high priest, as well as the spirit of all the remnant of the people. And they came and began the work on the house of the LORD of Hosts, their God,
Context
12Nígbà náà ni Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli, Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ìyókù, gba ohùn Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́ àti ọ̀rọ̀ wòlíì Hagai, nítorí Olúwa Ọlọ́run ni ó rán an. Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa. 13Nígbà náà ni Hagai ìránṣẹ́ Olúwa ń jíṣẹ́ Olúwa fún àwọn ènìyàn pé, “Èmí wà pẹ̀lú yín,” ni Olúwa wí. 14Nítorí náà, Olúwa ru ẹ̀mí Serubbabeli ọmọ Ṣealitieli sókè, baálẹ̀ Juda àti ẹ̀mí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù. Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn, 15ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì ọba Dariusi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.