Gẹnẹsisi 7:16
Genesis 7:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Gbogbo wọ́n wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa, Olúwa sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀.
Genesis 7:16 in English
Genesis 7:16 · Berean Standard Bible
And they entered, the male and female of every living thing, as God had commanded Noah. Then the LORD shut him in.
Context
14Wọ́n mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn. 15Méjì méjì ni gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè nínú wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀. 16Gbogbo wọ́n wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa, Olúwa sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀. 17Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i. 18Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.