Native Bible

Genesis 50:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Ejibiti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́.

Genesis 50:3 in English

Genesis 50:3 · Berean Standard Bible

taking the forty days required to complete the embalming. And the Egyptians mourned for him seventy days.

Context

1Josẹfu sì ṣubú lé baba rẹ̀, ó sọkún, ó sì fẹnukò ó ní ẹnu. 2Nígbà náà ni Josẹfu pàṣẹ fún àwọn oníṣègùn tí ó wà ní ìkáwọ́ rẹ̀ pé kí wọn kí ó ṣe òkú Israẹli baba rẹ̀ lọ́jọ̀, àwọn oníṣègùn náà sì ṣe bẹ́ẹ̀. 3Fún ogójì ọjọ́ ni wọ́n fi ṣe èyí, nítorí èyí ni àsìkò tí a máa ń fi ṣe ẹ̀ǹbáàmù òkú. Àwọn ará Ejibiti sì ṣọ̀fọ̀ rẹ̀ fún àádọ́rin ọjọ́. 4Nígbà tí ọjọ́ ìṣọ̀fọ̀ náà kọjá. Josẹfu wí fún àwọn ará ilé Farao pé, “Bí mo bá bá ojúrere yín pàdé, ẹ bá mi sọ fún Farao. 5‘Baba mi mú mi búra ó sì wí fún mi pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú: sinmi sínú ibojì tí mo gbẹ́ fún ara mi ní ilẹ̀ Kenaani.” Nísinsin yìí, jẹ́ kí n lọ kí n sì sìnkú baba mi, lẹ́yìn náà èmi yóò padà wa.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.