Gẹnẹsisi 50:23
Genesis 50:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì rí ìran kẹta ọmọ Efraimu-Àwọn ọmọ Makiri, ọmọkùnrin Manase ni a sì gbé le eékún Josẹfu nígbà tí ó bí wọn.
Genesis 50:23 in English
Genesis 50:23 · Berean Standard Bible
He saw Ephraim’s sons to the third generation, and indeed the sons of Machir son of Manasseh were brought up * on Joseph’s knees.
Context
21Nítorí náà, ẹ má ṣe bẹ̀rù. Èmi yóò pèsè fún ẹ̀yin àti àwọn ọmọ yín.” Ó tún fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, ó sì sọ ọ̀rọ̀ rere fun wọn. 22Josẹfu sì ń gbé ní Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ìdílé baba rẹ̀. Ó sì wà láààyè fún àádọ́fà ọdún. 23Ó sì rí ìran kẹta ọmọ Efraimu-Àwọn ọmọ Makiri, ọmọkùnrin Manase ni a sì gbé le eékún Josẹfu nígbà tí ó bí wọn. 24Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Mo ti fẹ́rẹ kú, ṣùgbọ́n dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, yóò sì mú un yín jáde kúrò ní ilẹ̀ yìí lọ sí ilẹ̀ tí ó ti ṣèlérí ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu.” 25Josẹfu sì mú kí àwọn ọmọ Israẹli búra májẹ̀mú kan wí pé, “Dájúdájú Ọlọ́run yóò wá sí ìrànlọ́wọ́ yín, nígbà náà ni ẹ gbọdọ̀ kó egungun mi lọ́wọ́ kúrò ní ìhín.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.