Gẹnẹsisi 47:4
Genesis 47:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n sì tún sọ fun un síwájú sí i pé, “A wá láti gbé ìhín yìí fún ìgbà díẹ̀ nítorí ìyàn náà mú púpọ̀ ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ohun ọ̀sìn àwa ìránṣẹ́ rẹ kò sì rí ewéko jẹ. Nítorí náà jọ̀wọ́ má ṣàì jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tẹ̀dó sí ilẹ̀ Goṣeni.”
Genesis 47:4 in English
Genesis 47:4 · Berean Standard Bible
Then they said to Pharaoh, “We have come to live in the land for a time, because there is no pasture for the flocks of your servants, since the famine in the land of Canaan has been severe. So now, please allow your servants to settle in the land of Goshen.”
Context
2Ó yan márùn-ún àwọn arákùnrin rẹ́, ó sì fi wọ́n han Farao. 3Farao béèrè lọ́wọ́ àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Kí ni iṣẹ́ yín?”
Wọ́n sì fèsì pé, “Darandaran ni àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wa ti jẹ́ darandaran.” 4Wọ́n sì tún sọ fun un síwájú sí i pé, “A wá láti gbé ìhín yìí fún ìgbà díẹ̀ nítorí ìyàn náà mú púpọ̀ ní ilẹ̀ Kenaani, àwọn ohun ọ̀sìn àwa ìránṣẹ́ rẹ kò sì rí ewéko jẹ. Nítorí náà jọ̀wọ́ má ṣàì jẹ́ kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ tẹ̀dó sí ilẹ̀ Goṣeni.” 5Farao wí fún Josẹfu pé, “Baba rẹ àti àwọn arákùnrin rẹ tọ̀ ọ́ wá, 6ilẹ̀ Ejibiti sì nìyí níwájú rẹ, mú àwọn arákùnrin rẹ tẹ̀dó sí ibi tí ó dára jù nínú ilẹ̀ náà. Jẹ́ kí wọn máa gbé ní Goṣeni. Bí o bá sì mọ ẹnikẹ́ni nínú wọn tí ó ní ẹ̀bùn ìtọ́jú ẹran, fi wọ́n ṣe olùtọ́jú ẹran ọ̀sìn mi.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.