Native Bible

Genesis 47:21 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Josẹfu sì sọ gbogbo ará Ejibiti di ẹrú láti igun kan dé èkejì.

Genesis 47:21 in English

Genesis 47:21 · Berean Standard Bible

and Joseph reduced the people to servitude * from one end of Egypt to the other.

Context

19Èéṣe tí àwa yóò fi parun lójú rẹ, ra àwa tìkára wa àti ilẹ̀ wa ní ìpààrọ̀ fún oúnjẹ, àwa àti ilẹ̀ wa yóò sì wà nínú ìgbèkùn Farao. Fún wa ni oúnjẹ kí àwa kí ó má ba à kú, kí ilẹ̀ wa má ba à di ahoro.” 20Nítorí náà Josẹfu ra gbogbo ilẹ̀ tí ó wà ní Ejibiti fún Farao, kò sí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù ní Ejibiti tí kò ta ilẹ̀ tirẹ̀ nítorí ìyàn náà mú jù fún wọn. Gbogbo ilẹ̀ náà sì di ti Farao, 21Josẹfu sì sọ gbogbo ará Ejibiti di ẹrú láti igun kan dé èkejì. 22Ṣùgbọ́n ṣá, kò ra ilẹ̀ àwọn àlùfáà, nítorí wọ́n ń gba ìpín oúnjẹ lọ́wọ́ Farao, wọn sì ní oúnjẹ tí ó tó láti inú ìpín tí Farao ń fún wọn. Ìdí nìyí tí wọn kò fi ta ilẹ̀ wọn. 23Josẹfu wí fún àwọn ènìyàn náà pé, “Níwọ́n ìgbà tí mo ti ra ẹ̀yin àti ilẹ̀ yín tan lónìí fún Farao, irúgbìn rèé, ẹ lọ gbìn ín sí ilẹ̀ náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.