Native Bible

Genesis 46:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Ejibiti, èmi yóò sì tún mú ọ padà wá. Ọwọ́ Josẹfu fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.”

Genesis 46:4 in English

Genesis 46:4 · Berean Standard Bible

I will go down with you to Egypt, and I will surely bring you back. And Joseph’s own hands will close your eyes.”

Context

2Ọlọ́run sì bá Israẹli sọ̀rọ̀ ní ojú ìran ní òru pé, “Jakọbu! Jakọbu!” Ó sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.” 3Ọlọ́run sì wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run, Ọlọ́run baba rẹ, má ṣe bẹ̀rù láti sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti nítorí, èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá níbẹ̀. 4Èmi yóò sì sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú rẹ lọ sí Ejibiti, èmi yóò sì tún mú ọ padà wá. Ọwọ́ Josẹfu fúnra rẹ̀ ni ìwọ yóò sì kú sí.” 5Nígbà náà ni Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, àwọn ọmọ Israẹli sì mú Jakọbu baba wọn àti àwọn aya wọn àti àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì kó wọn sí inú kẹ̀kẹ́ ẹrù tí Farao fi ránṣẹ́ fún ìrìnàjò rẹ̀. 6Wọ́n tún kó àwọn ohun ọ̀sìn wọn àti gbogbo ohun ìní tí wọ́n ti ní láti ilẹ̀ Kenaani, Jakọbu àti gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.