Gẹnẹsisi 45:2
Genesis 45:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì sọkún sókè kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ejibiti gbọ́ ohùn ẹkún rẹ̀, àwọn ilé Farao pẹ̀lú sì gbọ́ nípa rẹ̀.
Genesis 45:2 in English
Genesis 45:2 · Berean Standard Bible
But he wept so loudly that the Egyptians heard him, and Pharaoh’s household soon heard of it.
Context
1Josẹfu kò sì le è pa á mọ́ra mọ́ níwájú gbogbo àwọn tí ó dúró tì í. Ó sì sọkún sókè tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn tí ó wà ní àyíká gbọ́ ohun ẹkún rẹ̀. “Jẹ́ kí gbogbo ènìyàn kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.” Kò sì sí ẹnikẹ́ni lọ́dọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀. 2Ó sì sọkún sókè kíkankíkan tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn Ejibiti gbọ́ ohùn ẹkún rẹ̀, àwọn ilé Farao pẹ̀lú sì gbọ́ nípa rẹ̀. 3Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èmi ni Josẹfu! Ṣe baba mi sì wà láààyè?” Ṣùgbọ́n àwọn arákùnrin rẹ̀ kò le è dá a lóhùn nítorí ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi, ẹnu sì yà wọ́n níwájú rẹ̀. 4Nígbà náà ni Josẹfu wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi.” Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Èmi ni Josẹfu arákùnrin yín tí ẹ tà sí ilẹ̀ Ejibiti!
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.