Native Bible

Genesis 44:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olúwa mi béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ó ní baba tàbí arákùnrin?’

Genesis 44:19 in English

Genesis 44:19 · Berean Standard Bible

My lord asked his servants, ‘Do you have a father or a brother?’

Context

17Ṣùgbọ́n Josẹfu dáhùn pé, “Ká má rí i pé mo ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀! Ẹni tí a bá kọ́ọ̀bù mi lọ́wọ́ rẹ̀ nìkan ni yóò di ẹrú mi, ẹ̀yin tí ó kù, ẹ máa lọ sọ́dọ̀ baba yín ní àlàáfíà.” 18Nígbà náà ni Juda súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ olúwa mi, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ kí ó sọ ọ̀rọ̀ kan fún olúwa mi, má ṣe bínú sí ìránṣẹ́ rẹ bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ pẹ̀lú láṣẹ bí i ti Farao. 19Olúwa mi béèrè lọ́wọ́ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ó ní baba tàbí arákùnrin?’ 20Àwa sì wí fún olúwa mi pé, ‘A ni baba tí ó ti darúgbó, ọmọkùnrin kan sì wà pẹ̀lú tí a bí fún un ní ọjọ́ ogbó rẹ̀. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀, baba rẹ̀ sì fẹ́ràn án rẹ̀.’ 21“Nígbà náà ni ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, ‘Ẹ mu un tọ̀ mí wá kí n le fojú ara mi rí i.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.