Native Bible

Genesis 43:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ẹ̀rù sì ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Josẹfu. Wọ́n rò ó pé, “A mú wa wá sí ìhín nítorí owó tí a fi sí inú àpò wa ní ìgbà àkọ́kọ́. Ó fẹ́ bá wa jà, kí ó mú wa lẹ́rú kí ó sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.”

Genesis 43:18 in English

Genesis 43:18 · Berean Standard Bible

But the brothers were frightened that they had been taken to Joseph’s house. “We have been brought here because of the silver that was returned in our bags the first time,” they said. “They intend to overpower us and take us as slaves, along with our donkeys.”

Context

16Nígbà tí Josẹfu rí Benjamini pẹ̀lú wọn, ó sọ fún ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, “Mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí lọ sí ilé mi, pa ẹran kí o sì ṣe àsè; wọn ó jẹun ọ̀sán pẹ̀lú mi.” 17Ọkùnrin náà sì ṣe bí Josẹfu ti wí fún un, ó sì mú àwọn ọkùnrin náà lọ sí ilé Josẹfu. 18Ẹ̀rù sì ba àwọn ọkùnrin náà nígbà tí wọ́n mú wọn lọ sí ilé Josẹfu. Wọ́n rò ó pé, “A mú wa wá sí ìhín nítorí owó tí a fi sí inú àpò wa ní ìgbà àkọ́kọ́. Ó fẹ́ bá wa jà, kí ó mú wa lẹ́rú kí ó sì gba àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wa.” 19Nítorí náà wọ́n lọ bá ìránṣẹ́ Josẹfu, wọ́n sì ba sọ̀rọ̀ ní ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé ilé náà. 20Wọ́n wí pé, “Jọ̀wọ́ ọ̀gá, ní òtítọ́ ni àwa ti sọ̀kalẹ̀ síyìn-ín láti wá ra oúnjẹ ní ìṣáájú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.