Gẹnẹsisi 42:36
Genesis 42:36 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jakọbu baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Josẹfu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì rí Simeoni náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Benjamini lọ. Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí!”
Genesis 42:36 in English
Genesis 42:36 · Berean Standard Bible
Their father Jacob said to them, “You have deprived me of my sons. Joseph is gone and Simeon is no more. Now you want to take Benjamin. Everything is going against me!”
Context
34Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jùlọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́. Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín padà fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí.’ ” 35Bí wọ́n sì ti ń tú àpò ẹrù wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan bá owó tí ó san fún ọjà náà lẹ́nu àpò rẹ̀! Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, àwọn àti baba wọn. 36Jakọbu baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Josẹfu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì rí Simeoni náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Benjamini lọ. Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí!” 37Nígbà náà ni Reubeni wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi méjèèjì bí n kò bá mú Benjamini padà wá fún ọ, èmi ni kí o fà á lé lọ́wọ́, n ó sì mu un padà wá.” 38Ṣùgbọ́n Jakọbu wí pé, “Ọmọ mi kì yóò bá a yín lọ, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀. Bí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí i, ìbànújẹ́ ni yóò sì pa mi kú ni ọjọ́ ogbó mi yìí.”
42.9 tí ó túmọ̀ sí, Ayọ́lẹ̀wò
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.