Gẹnẹsisi 41:8
Genesis 41:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní òwúrọ̀, ọkàn rẹ̀ dàrú, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn onídán àti ọ̀mọ̀ran ilẹ̀ Ejibiti. Farao rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n kò rí ọ̀kan nínú wọn tí ó le sọ ìtumọ̀ àlá náà fún un.
Genesis 41:8 in English
Genesis 41:8 · Berean Standard Bible
In the morning his spirit was troubled, so he summoned all the magicians and wise men of Egypt. Pharaoh told them his dreams, but no one could interpret them for him.
Context
6Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yómọ, afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù. 7Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ (ọmọ rẹ̀ kò tóbi) wọ̀nyí sì gbé àwọn tí ó yómọ (ọmọ rẹ̀ tóbi) mì. Nígbà náà ni Farao jí lójú oorun, ó sì rí i pé àlá ni. 8Ní òwúrọ̀, ọkàn rẹ̀ dàrú, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn onídán àti ọ̀mọ̀ran ilẹ̀ Ejibiti. Farao rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n kò rí ọ̀kan nínú wọn tí ó le sọ ìtumọ̀ àlá náà fún un. 9Nígbà náà ni olórí agbọ́tí wí fún Farao pé, “Lónìí ni mo rántí ẹ̀ṣẹ̀ mi. 10Nígbà kan tí Farao bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi èmi àti olórí alásè sínú ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.