Gẹnẹsisi 40:9
Genesis 40:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Josẹfu, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi,
Genesis 40:9 in English
Genesis 40:9 · Berean Standard Bible
So the chief cupbearer told Joseph his dream: “In my dream there was a vine before me,
Context
7Ó sì bi àwọn ìjòyè Farao tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìhámọ́, nínú ilé olúwa rẹ̀ léèrè pé, “Èéṣe tí ojú yín fi fàro bẹ́ẹ̀ ní òní, tí inú yín kò sì dùn?” 8Wọ́n wí pé, “Àwa méjèèjì ni a lá àlá, kò sì sí ẹni tí yóò túmọ̀ rẹ̀.”
Josẹfu sì wí fún wọn pé, “Ọlọ́run nìkan ni ó ni ìtumọ̀. Ẹ sọ àwọn àlá yín fún mi.” 9Olórí agbọ́tí sì ṣọ́ àlá rẹ̀ fún Josẹfu, wí pé, “Ní ojú àlá mi, mo rí àjàrà kan (tí wọn ń fi èso rẹ̀ ṣe wáìnì) níwájú mi, 10mo sì rí ẹ̀ka mẹ́ta lórí àjàrà náà, ó yọ ẹ̀ka tuntun, ó sì tanná, láìpẹ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní í ní èso tí ó ti pọ́n. 11Ife Farao sì wà lọ́wọ́ mi, mo sì mú àwọn èso àjàrà náà, mo sì fún un sínú ife Farao, mo sì gbé ife náà fún Farao.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.