Native Bible

Genesis 39:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Josẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà.

Genesis 39:10 in English

Genesis 39:10 · Berean Standard Bible

Although Potiphar’s wife spoke to Joseph day after day, he refused to go to bed with her or even be near her.

Context

8Ṣùgbọ́n Josẹfu kọ̀, ó sì wí fún aya ọ̀gá rẹ̀ pé, “Kíyèsi, Olúwa mi kò fi ohunkóhun dù mi nínú ilé yìí, gbogbo ohun ìní rẹ̀ ni ó fi lé mi lọ́wọ́. 9Kò sí ẹni tí ó jù mi lọ nínú ilé yìí, ọ̀gá mi kò fi ohunkóhun dù mi àyàfi ìwọ, tí í ṣe aya rẹ̀. Báwo ni mo ṣe lè ṣe ohun búburú yìí, kí ń sì ṣẹ̀ sí Ọlọ́run?” 10Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ó ń tẹnumọ́ èyí fún Josẹfu, Josẹfu kọ̀ láti bá a lòpọ̀. Ó tilẹ̀ kọ̀ láti máa dúró ni ibi tí ó bá wà. 11Ní ọjọ́ kan, Josẹfu lọ sínú ilé láti ṣe iṣẹ́, kò sì sí èyíkéyìí nínú àwọn ìránṣẹ́ ní tòsí. 12Ó sì di aṣọ Josẹfu mú, ó sì wí pé, “Wá bá mi lòpọ̀!” Ṣùgbọ́n Josẹfu fi aṣọ rẹ̀ sílẹ̀ sí i lọ́wọ́, ó sì sá jáde.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.