Native Bible

Genesis 38:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Juda sì dá wọn mọ̀, ó sì wí pé, “O ṣe olódodo jù mí lọ, níwọ̀n ìgbà tí n kò fi fún Ṣela ọmọ mi.” Kò sì bá a lòpọ̀ mọ́ láti ọjọ́ náà.

Genesis 38:26 in English

Genesis 38:26 · Berean Standard Bible

Judah recognized the items and said, “She is more righteous than I, since I did not give her to my son Shelah.” And he did not have relations with her again.

Context

24Lẹ́yìn nǹkan bí oṣù mẹ́ta, wọn sọ fún Juda pé, “Tamari aya ọmọ rẹ̀ ṣe àgbèrè, ó sì ti lóyún.” Juda sì wí pé, “Ẹ mú un jáde, kí ẹ sì dá iná sun ún.” 25Bí wọ́n sì ti ń mú un jáde, ó ránṣẹ́ sí baba ọkọ rẹ̀ pé, “Ọkùnrin tí ó ni àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó fún mi lóyún. Wò ó, bóyá o lè mọ ẹni tí ó ni èdìdì ìdámọ̀, okùn àti ọ̀pá ìtìlẹ̀ wọ̀nyí.” 26Juda sì dá wọn mọ̀, ó sì wí pé, “O ṣe olódodo jù mí lọ, níwọ̀n ìgbà tí n kò fi fún Ṣela ọmọ mi.” Kò sì bá a lòpọ̀ mọ́ láti ọjọ́ náà. 27Nígbà tí àsìkò ìbímọ rẹ̀ tó. Ìbejì ọkùnrin ni ó bí. 28Bí ó sì ti ń bímọ, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ náà na ọwọ́ jáde; agbẹ̀bí sì so okùn òdòdó mọ́ ọmọ náà ní ọrùn ọwọ́. Ó sì wí pé, “Èyí ni o kọ́kọ́ jáde.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.