Gẹnẹsisi 38:14
Genesis 38:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́n. Ó sì jókòó sí ẹnu-bodè Enaimu, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Timna. Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣela ti dàgbà, síbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya.
Genesis 38:14 in English
Genesis 38:14 · Berean Standard Bible
she removed her widow’s garments, covered her face with a veil to disguise herself, and sat at the entrance to Enaim, which is on the way to Timnah. For she saw that although Shelah had grown up, she had not been given to him as a wife.
Context
12Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Juda, ọmọbìnrin Ṣua sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Juda sì pé, ó gòkè lọ sí Timna, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hira ará Adullamu tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ. 13Nígbà tí ẹnìkan sọ fún Tamari pé, “Baba ọkọ ọ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀nà àjò rẹ̀ sí Timna láti rẹ́run àgùntàn rẹ̀.” 14Ó bọ́ aṣọ opó rẹ̀, ó sì fi ìbòjú bo ojú ara rẹ̀ kí wọn má ba à mọ̀ ọ́n. Ó sì jókòó sí ẹnu-bodè Enaimu, èyí tí ó wà ní ọ̀nà Timna. Nítorí ó rí i wí pé, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ṣela ti dàgbà, síbẹ̀, a kò fi òun fún un gẹ́gẹ́ bí aya. 15Nígbà tí Juda rí i, ó rò pé panṣágà ni, nítorí ó ti bo ojú rẹ̀. 16Láìmọ̀ pé, aya ọmọ òun ní í ṣe, ó yà tọ̀ ọ́ ní ẹ̀bá ọ̀nà, ó wí pé, “Wá kí èmi kí ó lè wọlé tọ̀ ọ́.”
Òun sì wí pé, “Kín ni ìwọ yóò fi fún mi kí ìwọ kó lè wọlé tọ̀ mí.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.