Gẹnẹsisi 38:11
Genesis 38:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Juda wí fún Tamari, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Lọ máa gbé bí opó ní ilé baba rẹ, títí tí Ṣela yóò fi dàgbà ó lérò pé òun náà lè kú bí àwọn arákùnrin rẹ̀ tókù.” Nígbà náà ni Tamari ń lọ gbé ilé baba rẹ̀.
Genesis 38:11 in English
Genesis 38:11 · Berean Standard Bible
Then Judah said to his daughter-in-law Tamar, “Live as a widow in your father’s house until my son Shelah grows up.” For he thought, “He may die too, like his brothers.” So Tamar went to live in her father’s house.
Context
9Ṣùgbọ́n Onani mọ̀ pé àwọn ọmọ náà kì yóò jẹ́ ti òun, nítorí náà ni gbogbo ìgbà tí ó bá wọlé tọ aya arákùnrin rẹ̀ lọ, ilẹ̀ ni ó ń da nǹkan ọkùnrin rẹ̀ sí, kí ó má bá a bímọ fún arákùnrin rẹ̀. 10Ohun tí ó ń ṣe yìí burú lójú Olúwa, ó sì pa òun náà pẹ̀lú. 11Nígbà náà ni Juda wí fún Tamari, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Lọ máa gbé bí opó ní ilé baba rẹ, títí tí Ṣela yóò fi dàgbà ó lérò pé òun náà lè kú bí àwọn arákùnrin rẹ̀ tókù.” Nígbà náà ni Tamari ń lọ gbé ilé baba rẹ̀. 12Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ìyàwó Juda, ọmọbìnrin Ṣua sì kú, nígbà tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ Juda sì pé, ó gòkè lọ sí Timna, sí ọ̀dọ̀ àwọn tí ń bá a rẹ́run àgùntàn rẹ̀, Hira ará Adullamu tí í ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì bá a lọ. 13Nígbà tí ẹnìkan sọ fún Tamari pé, “Baba ọkọ ọ̀ rẹ̀ wà ní ọ̀nà àjò rẹ̀ sí Timna láti rẹ́run àgùntàn rẹ̀.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.