Native Bible

Genesis 37:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

O wí fún wọn pé, “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá,

Genesis 37:6 in English

Genesis 37:6 · Berean Standard Bible

He said to them, “Listen to this dream I had:

Context

4Nígbà tí àwọn arákùnrin rẹ̀ rí i pé baba àwọn fẹ́ràn rẹ̀ ju gbogbo wọn lọ, wọ́n kórìíra rẹ̀, wọ́n sì ń fi ẹ̀tanú bá a gbé, kò sì sí àlàáfíà láàrín wọn. 5Josẹfu lá àlá kan, nígbà tí ó sì sọ fún àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i. 6O wí fún wọn pé, “Ẹ fetí sí àlá tí mo lá, 7sá à wò ó, àwa ń yí ìtí ọkà nínú oko, ó sì ṣe ìtí ọkà tèmi sì dìde dúró ṣánṣán, àwọn ìtí ọkà tiyín sì dúró yí ìtí tèmi ká, wọ́n sì ń foríbalẹ̀ fún un.” 8Àwọn arákùnrin rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ ń gbèrò àti jẹ ọba lé wa lórí bí? Tàbí ìwọ ó ṣe olórí wa nítòótọ́?” Wọn sì túbọ̀ kórìíra rẹ̀ sí i, nítorí àlá rẹ̀ àti nítorí ohun tí ó wí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.