Gẹnẹsisi 37:25
Genesis 37:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bí wọ́n sì ti jókòó láti jẹun, wọ́n gbójú sókè, wọ́n sì rí àwọn oníṣòwò ará Iṣmaeli tí wọ́n ń wọ́ bọ̀ láti Gileadi. Ìbákasẹ wọn sì ru tùràrí, ìkunra àti òjìá, wọ́n ń lọ sí Ejibiti.
Genesis 37:25 in English
Genesis 37:25 · Berean Standard Bible
And as they sat down to eat a meal, they looked up and saw a caravan of Ishmaelites coming from Gilead. Their camels were carrying spices, balm, and myrrh on their way down to Egypt.
Context
23Nítorí náà, nígbà tí Josẹfu dé ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n bọ́ ẹ̀wù rẹ̀—Ẹ̀wù ọlọ́nà, aláràbarà tí ó wọ̀— 24wọ́n mú un, wọ́n sì jù ú sínú kòtò. Kòtò náà sì ṣófo, kò sí omi nínú rẹ̀. 25Bí wọ́n sì ti jókòó láti jẹun, wọ́n gbójú sókè, wọ́n sì rí àwọn oníṣòwò ará Iṣmaeli tí wọ́n ń wọ́ bọ̀ láti Gileadi. Ìbákasẹ wọn sì ru tùràrí, ìkunra àti òjìá, wọ́n ń lọ sí Ejibiti. 26Juda wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “Èrè kí ni ó jẹ́ bí a bá pa arákùnrin wa tí a bo ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ ti ọkàn wa sì ń dá wa lẹ́bi? 27Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á tà á fún àwọn ará Iṣmaeli, kí àwa má sì pa á, ṣè bí àbúrò wa ni, ẹran-ara wa àti ẹ̀jẹ̀ wa ní i ṣe.” Àwọn arákùnrin rẹ̀ sì fi ara mọ́ ohun tí ó sọ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.