Gẹnẹsisi 35:7
Genesis 35:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Beteli,* nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arákùnrin rẹ̀.
Genesis 35:7 in English
Genesis 35:7 · Berean Standard Bible
There Jacob built an altar, and he called that place El-bethel,* because it was there that God had revealed Himself to Jacob as he fled from his brother.
Context
5Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn. Ìbẹ̀rù Ọlọ́run sì ń bẹ lára gbogbo ìlú tí ó yí wọn ká, wọ́n kò sì lépa àwọn ọmọ Jakọbu. 6Jakọbu àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sì dé sí Lusi (ti o túmọ̀ sí Beteli) tí ó wà ní ilẹ̀ Kenaani. 7Níbẹ̀ ni ó sì mọ pẹpẹ kan tí ó pè ní El-Beteli,* nítorí níbẹ̀ ni Ọlọ́run ti gbé fi ara hàn án nígbà tí ó ń sálọ fún arákùnrin rẹ̀. 8Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Debora, olùtọ́jú Rebeka kú, a sì sin ín sábẹ́ igi óákù ní ìsàlẹ̀ Beteli. Nítorí náà a sọ ọ́ ní Aloni-Bakuti. 9Lẹ́yìn tí Jakọbu padà dé láti Padani-Aramu, Ọlọ́run tún fi ara hàn án, ó sì súre fún un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.