Gẹnẹsisi 35:14
Genesis 35:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jakọbu sì fi òkúta ṣe ọ̀wọ̀n kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀, ó sì ta ọrẹ ohun mímu sí orí rẹ̀, ó sì da òróró olifi sí orí rẹ̀ pẹ̀lú.
Genesis 35:14 in English
Genesis 35:14 · Berean Standard Bible
So Jacob set up a pillar in the place where God had spoken with him—a stone marker—and he poured out a drink offering on it and anointed it with oil.
Context
12Gbogbo ilẹ̀ tí mo fi fún Abrahamu àti Isaaki ni èmi yóò fún ọ pẹ̀lú, àti fún àwọn ìran rẹ tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn.” 13Nígbà náà ni Ọlọ́run gòkè lọ kúrò ní ibi tí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀. 14Jakọbu sì fi òkúta ṣe ọ̀wọ̀n kan sí ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀, ó sì ta ọrẹ ohun mímu sí orí rẹ̀, ó sì da òróró olifi sí orí rẹ̀ pẹ̀lú. 15Jakọbu sì pe orúkọ ibi tí Ọlọ́run ti bá a sọ̀rọ̀ ní Beteli. 16Nígbà náà ni wọ́n ń tẹ̀síwájú nínú ìrìnàjò wọn láti Beteli. Nígbà tí ó sì ku díẹ̀ kí wọn dé Efrata, Rakeli bẹ̀rẹ̀ sí ní rọbí, ó sì ní ìdààmú púpọ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.