Native Bible

Genesis 32:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì.

Genesis 32:25 in English

Genesis 32:25 · Berean Standard Bible

When the man saw that he could not overpower Jacob, he struck the socket of Jacob’s hip and dislocated it as they wrestled.

Context

23Lẹ́yìn ìgbà tí ó ti rán wọn kọjá odò tán sí òkè odò, ó sì rán àwọn ohun ìní rẹ̀ kọjá pẹ̀lú. 24Ó sì ku Jakọbu nìkan, ọkùnrin kan sì bá a ja ìjàkadì títí ó fi di àfẹ̀mọ́júmọ́. 25Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkùnrin náà rí i pé òun kò le borí Jakọbu, ó fọwọ́ kàn án ní ọ̀ọ́kán ibi tí eegun itan ti bẹ̀rẹ̀, egungun náà sì yẹ̀ kúrò lórí ike, bí ó ti ń ja ìjàkadì. 26Nígbà náà ni ọkùnrin náà wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń máa lọ, nítorí ojúmọ́ ti mọ́.” Ṣùgbọ́n Jakọbu dá a lóhùn pé, “Èmi kò ní jẹ́ kí o lọ, àyàfi bí o bá súre fún mi.” 27Ọkùnrin náà béèrè orúkọ rẹ̀. Ó sì wí fún un pé, “Jakọbu ni òun ń jẹ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.