Gẹnẹsisi 31:35
Genesis 31:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Rakeli sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Má ṣe bínú pé èmi ò le dìde dúró níwájú rẹ baba à mi, ohun tí ó fà á ni pé, mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.” Ó sì wá àgọ́ kiri, kò sì rí àwọn òrìṣà ìdílé náà.
Genesis 31:35 in English
Genesis 31:35 · Berean Standard Bible
Rachel said to her father, “Sir, do not be angry that I cannot stand up before you; for I am having my period.” So Laban searched, but could not find the household idols.
Context
33Labani sì lọ sínú àgọ́ Jakọbu àti ti Lea àti ti àwọn ìránṣẹ́bìnrin méjèèjì, kò sì rí ohunkóhun. Lẹ́yìn ìgbà tí ó jáde nínú àgọ́ Lea ni ó lọ sí àgọ́ Rakeli. 34Rakeli sì gbé àwọn òrìṣà náà sínú gàárì ìbákasẹ, ó sì jókòó lé e lórí. Labani sì wá gbogbo inú àgọ́, kò sì rí ohunkóhun. 35Rakeli sì wí fún baba rẹ̀ pé, “Má ṣe bínú pé èmi ò le dìde dúró níwájú rẹ baba à mi, ohun tí ó fà á ni pé, mò ń ṣe nǹkan oṣù lọ́wọ́.” Ó sì wá àgọ́ kiri, kò sì rí àwọn òrìṣà ìdílé náà. 36Inú sì bí Jakọbu, ó sì pe Labani ní ìjà pé, “Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ mi? Ẹ̀ṣẹ̀ wo ni mo ṣẹ̀ ọ tí ìwọ fi ń lépa mi bí ọ̀daràn? 37Nísinsin yìí tí ìwọ ti tú gbogbo ẹrù mi wò, kí ni ohun tí í ṣe tirẹ̀ tí ìwọ rí? Kó wọn kalẹ̀ báyìí níwájú gbogbo ìbátan rẹ àti tèmi, kí wọn kí ó sì ṣe ìdájọ́ láàrín àwa méjèèjì.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.