Gẹnẹsisi 31:15
Genesis 31:15 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àjèjì ha kọ́ ni ó kà wá sí? Kì í ṣe torí pé ó tà wá nìkan, ṣùgbọ́n ó ti ná gbogbo owó tí ó gbà lórí wa tán.
Genesis 31:15 in English
Genesis 31:15 · Berean Standard Bible
Are we not regarded by him as outsiders? Not only has he sold us, but he has certainly squandered what was paid for us.
Context
13Èmi ni Ọlọ́run Beteli, níbi tí ìwọ ti ta òróró sí ọ̀wọ́n, ìwọ sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti sìn mi. Nísinsin yìí, kúrò ní ilẹ̀ yìí kíákíá kí o sì padà sí ilẹ̀ ibi tí a gbé ti bí ọ.’ ” 14Nígbà náà ni Rakeli àti Lea dáhùn pé, “Ìpín wo ní a ní nínú ogún baba wa? 15Àjèjì ha kọ́ ni ó kà wá sí? Kì í ṣe torí pé ó tà wá nìkan, ṣùgbọ́n ó ti ná gbogbo owó tí ó gbà lórí wa tán. 16Dájúdájú gbogbo ọrọ̀ ti Ọlọ́run gbà lọ́wọ́ baba wa fún ọ, tiwa àti ti àwọn ọmọ wa ní í ṣe. Nítorí náà ohun gbogbo tí Ọlọ́run bá pàṣẹ fun ọ láti ṣe ni kí ìwọ kí ó ṣe.” 17Nígbà náà ni Jakọbu gbé àwọn ọmọ àti aya rẹ̀ gun ìbákasẹ.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.