Native Bible

Genesis 30:41 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbàkígbà tí àwọn ẹran tí ó lera bá ń gùn, Jakọbu yóò fi àwọn ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú wọn, ní ibi tí wọn ti ń mu omi.

Genesis 30:41 in English

Genesis 30:41 · Berean Standard Bible

Whenever the stronger females of the flock were in heat, Jacob would place the branches in the troughs, in full view of the animals, so that they would breed in front of the branches.

Context

39Tí àwọn ẹran bá sì ń gùn, níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọn sì bí àwọn ẹran onílà àti alámì, àwọn tí ó ní tótòtó lára. 40Nígbà náà ni ó ya àwọn abo ẹran kúrò nínú agbo ẹran Labani, ó sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àgbò, ó sì mú kí wọn máa gùn pẹ̀lú àwọn àgbò Jakọbu dúdú nìkan, bẹ́ẹ̀ ni ó kó agbo ẹran jọ fún ara rẹ̀ láti ara agbo ẹran Labani. 41Nígbàkígbà tí àwọn ẹran tí ó lera bá ń gùn, Jakọbu yóò fi àwọn ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú wọn, ní ibi tí wọn ti ń mu omi. 42Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ wí pé wọn kò lera, kò ní fi àwọn ọ̀pá náà lélẹ̀. Nítorí náà, àwọn tí kò lera ń jẹ́ ti Labani, nígbà tí àwọn tí ó lera ń jẹ́ ti Jakọbu. 43Nítorí ìdí èyí, Jakọbu di ọlọ́rọ̀ gidigidi, agbo ẹran rẹ̀ pọ̀ àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin, ìránṣẹ́bìnrin pẹ̀lú ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.