Gẹnẹsisi 29:10
Genesis 29:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Jakọbu rí Rakeli ọmọbìnrin Labani tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Labani, Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Labani ní omi.
Genesis 29:10 in English
Genesis 29:10 · Berean Standard Bible
As soon as Jacob saw Rachel, the daughter of his mother’s brother Laban, with Laban’s sheep, he went up and rolled the stone away from the mouth of the well and watered his uncle’s sheep.
Context
8Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa kì í yí òkúta kúrò ní ẹnu kànga láti pọn omi fún àwọn ẹran títí gbogbo àwọn darandaran àti àwọn ẹran yóò fi péjọ tán.” 9Bí wọ́n sì ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́ ni Rakeli dé pẹ̀lú agbo àgùntàn baba rẹ̀, nítorí darandaran ni òun náà. 10Nígbà tí Jakọbu rí Rakeli ọmọbìnrin Labani tí í ṣe ẹ̀gbọ́n ìyá rẹ̀, pẹ̀lú àgùntàn Labani, Jakọbu súnmọ́ kànga náà, ó sì yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀, ó sì fún àwọn ẹran arákùnrin ìyá rẹ̀ Labani ní omi. 11Jakọbu sì fẹnu ko Rakeli ní ẹnu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọkún. 12Jakọbu sì wí fún Rakeli pé ìbátan baba rẹ̀ ni òun, àti pé, òun jẹ́ ọmọ Rebeka. Rakeli sì sáré lọ sọ fún baba rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.