Gẹnẹsisi 28:11
Genesis 28:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn.
Genesis 28:11 in English
Genesis 28:11 · Berean Standard Bible
On reaching a certain place, he spent the night there because the sun had set. And taking one of the stones from that place, he put it under his head and lay down to sleep.
Context
9Nítorí náà Esau tọ Iṣmaeli lọ, ó sì fẹ́ Mahalati, arábìnrin Nebaioti, ọmọbìnrin Iṣmaeli tí í ṣe ọmọ Abrahamu. Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀. 10Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani. 11Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. 12Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀. 13Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.