Native Bible

Genesis 27:42 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Rebeka sì gbọ́ ohun tí Esau àkọ́bí rẹ̀ wí, ó sì ránṣẹ́ sí Jakọbu, ó sì wí fun un pé, “Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú èrò à ti pa ọ́.

Genesis 27:42 in English

Genesis 27:42 · Berean Standard Bible

When the words of her older son Esau were relayed to Rebekah, she sent for her younger son Jacob and told him, “Look, your brother Esau is consoling himself by plotting to kill you.

Context

40Nípa idà rẹ ni ìwọ yóò máa gbé, ìwọ yóò sì máa sin àbúrò rẹ, ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, nígbà tí ìwọ bá di alágbára ìwọ yóò já àjàgà rẹ̀ kúrò lọ́rùn rẹ.” 41Esau sì kórìíra Jakọbu nítorí ìre tí baba rẹ̀ sú fún un, ó sì wí fún ara rẹ̀ pé, “Baba mi sá à ti fẹ́rẹ kú, nígbà náà ni èmi ó pa Jakọbu, arákùnrin mi.” 42Nígbà tí Rebeka sì gbọ́ ohun tí Esau àkọ́bí rẹ̀ wí, ó sì ránṣẹ́ sí Jakọbu, ó sì wí fun un pé, “Esau ẹ̀gbọ́n rẹ ń tu ara rẹ̀ nínú pẹ̀lú èrò à ti pa ọ́. 43Nítorí náà ọmọ mi, ṣe ohun tí èmi yóò sọ fún ọ, sálọ sọ́dọ̀ Labani ẹ̀gbọ́n mi ní Harani. 44Jókòó sí ibẹ̀ títí di ìgbà tí ìbínú ẹ̀gbọ́n rẹ yóò fi rọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.