Gẹnẹsisi 26:28
Genesis 26:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrín àwa àti ìwọ. Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn
Genesis 26:28 in English
Genesis 26:28 · Berean Standard Bible
“We can plainly see that the LORD has been with you,” they replied. “We recommend that there should now be an oath between us and you. Let us make a covenant with you
Context
26Nígbà náà ni Abimeleki tọ̀ ọ́ wá láti Gerari, àti Ahussati, olùdámọ̀ràn rẹ̀ àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀. 27Isaaki sì bi wọ́n léèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin tọ̀ mí wá, níwọ̀n ìgbà tí ẹ̀yin kórìíra mi tí ẹ sì lé mi jáde kúrò lọ́dọ̀ yín?” 28Wọ́n dáhùn pé, “A rí i dájú pé Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, nítorí náà ni a fi rò ó wí pé, ó yẹ kí májẹ̀mú kí o wà láàrín àwa àti ìwọ. Jẹ́ kí a ṣe àdéhùn 29pé ìwọ kì yóò ṣe wá ní ibi, bí àwa pẹ̀lú kò ti ṣe ọ́ ní aburú, tí a sì ń ṣe ọ́ dáradára, tí a sì rán ọ jáde ní àlàáfíà láìṣe ọ́ ní ibi, kíyèsi Olúwa sì ti bùkún fún ọ.” 30Isaaki sì ṣe àsè fún wọn, wọn sì jẹ, wọ́n sì mu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.