Native Bible

Genesis 23:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

bí ohun ìní fún Abrahamu níwájú gbogbo ará Hiti tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà.

Genesis 23:18 in English

Genesis 23:18 · Berean Standard Bible

to Abraham’s possession in the presence of all the Hittites who had come to the gate of his city.

Context

16Abrahamu sì gbọ́ tí Efroni wí, Abrahamu sì wọn iye fàdákà náà fún Efroni, tí ó sọ ní etí àwọn ọmọ Hiti, irinwó (400) òsùwọ̀n ṣékélì fàdákà, tí ó kọjá lọ́dọ̀ àwọn oníṣòwò. 17Báyìí ni ilẹ̀ Efroni tí ó wà ni Makpela nítòsí Mamre, ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ àti gbogbo igi tí ó wà nínú ilẹ̀ náà ni a ṣe ètò rẹ̀ dájú, 18bí ohun ìní fún Abrahamu níwájú gbogbo ará Hiti tí ó wá sí ẹnu ibodè ìlú náà. 19Lẹ́yìn náà ni Abrahamu sin aya rẹ̀ Sara sínú ihò àpáta ní ilẹ̀ Makpela nítòsí Mamre (tí í ṣe Hebroni) ní ilẹ̀ Kenaani. 20Ilẹ̀ náà àti ihò àpáta tí ó wà nínú rẹ̀ ni àwọn ará Hiti fi fún Abrahamu gẹ́gẹ́ bí ohun ìní títí láé, bí ilẹ̀ ìsìnkú fún àwọn òkú tí ó bá kú fun un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.