Gẹnẹsisi 20:6
Genesis 20:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un nínú àlá náà pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé pẹ̀lú òtítọ́ inú ni ìwọ ṣe èyí, èyí ni mo fi pa ọ́ mọ́ tí ń kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà.
Genesis 20:6 in English
Genesis 20:6 · Berean Standard Bible
Then God said to Abimelech in the dream, “Yes, I know that you did this with a clear conscience, and so I have kept you from sinning against Me. That is why I did not let you touch her.
Context
4Ṣùgbọ́n Abimeleki kò tí ìbá obìnrin náà lòpọ̀, nítorí náà ó wí pé, “Olúwa ìwọ yóò run orílẹ̀-èdè aláìlẹ́bi bí? 5Ǹjẹ́ òun kò sọ fún mi pé, ‘Arábìnrin mi ni,’ obìnrin náà pẹ̀lú sì sọ pé, ‘Arákùnrin mí ni’? Ní òtítọ́ pẹ̀lú ọkàn mímọ́ àti ọwọ́ mímọ́, ni mo ṣe èyí.” 6Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún un nínú àlá náà pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, mo mọ̀ pé pẹ̀lú òtítọ́ inú ni ìwọ ṣe èyí, èyí ni mo fi pa ọ́ mọ́ tí ń kò jẹ́ kí o ṣẹ̀ sí mi. Ìdí nìyí tí n kò fi jẹ́ kí o ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin náà. 7Nísinsin yìí, dá aya ọkùnrin náà padà, nítorí pé wòlíì ni, yóò sì gbàdúrà fún ọ, ìwọ yóò sì yè. Ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá dá a padà, mọ̀ dájú pé ìwọ àti gbogbo ẹni tí í ṣe tìrẹ yóò kú.” 8Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kejì, Abimeleki pe gbogbo àwọn ìjòyè rẹ̀. Nígbà tí ó sì sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún wọn, ẹ̀rù bà wọ́n gidigidi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.