Gẹnẹsisi 2:3
Genesis 2:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.
Genesis 2:3 in English
Genesis 2:3 · Berean Standard Bible
Then God blessed the seventh day and sanctified it, because on that day He rested from all the work of creation that He had accomplished.
Context
1Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀. 2Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe. 3Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe. 4Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run. 5Kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.