Gẹnẹsisi 2:19
Genesis 2:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́.
Genesis 2:19 in English
Genesis 2:19 · Berean Standard Bible
And out of the ground the LORD God formed every beast of the field and every bird of the air, and He brought them to the man to see what he would name each one. And whatever the man called each living creature, that was its name.
Context
17ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti èso igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kùú.” 18Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.” 19Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́. 20Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ.
Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀. 21Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.