Gẹnẹsisi 19:29
Genesis 19:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run sì rántí Abrahamu, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọti jáde kúrò láàrín ìparun náà, tí ó kọlu ìlú tí Lọti ti gbé.
Genesis 19:29 in English
Genesis 19:29 · Berean Standard Bible
So when God destroyed the cities of the plain, He remembered Abraham, and He brought Lot out of the catastrophe that destroyed the cities where he had lived.
Context
27Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, Abrahamu sì dìde ó sì padà lọ sí ibi tí ó gbé dúró níwájú Olúwa. 28Ó sì wo ìhà Sodomu àti Gomorra àti àwọn ilẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì, ó sì rí èéfín tí ń ti ibẹ̀ jáde bí èéfín iná ìléru. 29Ọlọ́run sì rántí Abrahamu, nígbà tí ó run ìlú pẹ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀n-ọn-nì tan, ó sì mú Lọti jáde kúrò láàrín ìparun náà, tí ó kọlu ìlú tí Lọti ti gbé. 30Lọti àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjèèjì sì kúrò ní Soari, wọ́n sì ń lọ gbé ní orí òkè ní inú ihò àpáta, nítorí ó bẹ̀rù láti gbé ní ìlú Soari. 31Ní ọjọ́ kan, èyí ẹ̀gbọ́n sọ fún àbúrò rẹ̀ pé, “Baba wa ti dàgbà, kò sì sí ọkùnrin kankan ní agbègbè yìí tí ìbá bá wa lòpọ̀, bí ìṣe gbogbo ayé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.