Gẹnẹsisi 19:12
Genesis 19:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn ọkùnrin náà sì wí fún Lọti pé, “Ǹjẹ́ ó ní ẹlòmíràn ní ìlú yìí bí? Àna rẹ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí ẹnikẹ́ni tí ìwọ ní ní ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò ní ibí yìí,
Genesis 19:12 in English
Genesis 19:12 · Berean Standard Bible
Then the two men said to Lot, “Do you have anyone else here—a son-in-law, your sons or daughters, or anyone else in the city who belongs to you? Get them out of here,
Context
10Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin náà nawọ́ fa Lọti wọlé, wọ́n sì ti ìlẹ̀kùn. 11Wọ́n sì bu ìfọ́jú lu àwọn ọkùnrin tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà ilé náà, àti èwe àti àgbà: wọ́n kò sì rí ẹnu-ọ̀nà mọ́. 12Àwọn ọkùnrin náà sì wí fún Lọti pé, “Ǹjẹ́ ó ní ẹlòmíràn ní ìlú yìí bí? Àna rẹ ọkùnrin, àwọn ọmọ rẹ lọ́kùnrin àti lóbìnrin, tàbí ẹnikẹ́ni tí ìwọ ní ní ìlú yìí, kó wọn jáde kúrò ní ibí yìí, 13nítorí a ó pa ìlú yìí run, nítorí igbe iṣẹ́ búburú wọn ń dí púpọ̀ níwájú Olúwa, Olúwa sì rán wa láti pa á run.” 14Nígbà náà ni Lọti jáde, ó sì wí fún àwọn àna rẹ̀ ọkùnrin tí ó ti bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ láti fẹ́ àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ ṣe kánkán, kí ẹ jáde ní ìlú yìí, nítorí Olúwa fẹ́ pa ìlú yìí run!” Ṣùgbọ́n àwọn ọkọ ọmọ rẹ̀ wọ̀nyí rò pé àwàdà ló ń ṣe.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.