Native Bible

Genesis 18:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí tí èmi ti yàn án láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ará ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, láti máa pa ọ̀nà Olúwa mọ nípa ṣíṣe olóòtítọ́ àti olódodo: kí Olúwa le è mú ìlérí rẹ̀ fún Abrahamu ṣẹ.”

Genesis 18:19 in English

Genesis 18:19 · Berean Standard Bible

For I have chosen him, so that he will command his children and his household after him to keep the way of the LORD by doing what is right and just, in order that the LORD may bring upon Abraham what He has promised.”

Context

17Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ǹjẹ́ èmi yóò ha pa ohun tí mo fẹ́ ṣe mọ́ fún Abrahamu bí? 18Dájúdájú Abrahamu yóò sá à di orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára, àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni a ó bùkún fún nípasẹ̀ rẹ̀. 19Nítorí tí èmi ti yàn án láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ará ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, láti máa pa ọ̀nà Olúwa mọ nípa ṣíṣe olóòtítọ́ àti olódodo: kí Olúwa le è mú ìlérí rẹ̀ fún Abrahamu ṣẹ.” 20Olúwa sì wí pé, igbe Sodomu àti Gomorra pọ̀ púpọ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jọjọ. 21“Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ síbẹ̀ láti ṣe ìwádìí igbe tí ó dé sí etí ìgbọ́ mi nípa wọn, kí èmi sì mọ òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.