Gẹnẹsisi 17:13
Genesis 17:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí o fi owó rà, a gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé.
Genesis 17:13 in English
Genesis 17:13 · Berean Standard Bible
Whether they are born in your household or purchased, they must be circumcised. My covenant in your flesh will be an everlasting covenant.
Context
11Ẹ̀yin yóò kọ ara yín ní ilà, èyí ni yóò jẹ́ àmì májẹ̀mú láàrín tèmi tiyín. 12Ní gbogbo ìran tí ń bọ̀ lẹ́yìn, gbogbo ọkùnrin ni a gbọdọ̀ kọ ni ilà ní ọjọ́ kẹjọ tí a bí wọn, àti àwọn tí a bí ní ilé rẹ, tàbí tí a fi owó rà lọ́wọ́ àwọn àjèjì, àwọn tí kì í ṣe ọmọ rẹ̀. Èyí yóò sì jẹ́ májẹ̀mú láéláé tí yóò wà láàrín Èmi àti irú-ọmọ rẹ. 13Ìbá à ṣe ẹni tí a bí nínú ilé rẹ, tàbí ẹni tí o fi owó rà, a gbọdọ̀ kọ wọ́n ní ilà; májẹ̀mú mí lára yín yóò jẹ́ májẹ̀mú ayérayé. 14Gbogbo ọmọkùnrin tí kò bá kọ ilà, tí a kò kọ ní ilà abẹ́, ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorí pé ó da májẹ̀mú mi.” 15Ọlọ́run wí fún Abrahamu pé, “Ní ti Sarai, aya rẹ̀, ìwọ kì yóò pè é ní Sarai mọ́, bí kò ṣe Sara.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.