Native Bible

Genesis 15:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé, “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnra rẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.”

Genesis 15:4 in English

Genesis 15:4 · Berean Standard Bible

Then the word of the LORD came to Abram, saying, “This one will not be your heir, but one who comes from your own body will be your heir.”

Context

2Ṣùgbọ́n Abramu wí pé, “Olúwa Olódùmarè, kí ni ìwọ yóò fi fún mi níwọ̀n ìgbà tí èmi kò bímọ, Elieseri ará Damasku ni yóò sì jogún mi,” 3Abramu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Ìwọ kò fún mi ní ọmọ, nítorí náà ẹrú nínú ilé mi sì ni yóò jẹ́ àrólé mi.” 4Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tún tọ̀ ọ́ wá pé, “Ọkùnrin yìí kọ́ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ bí kò ṣe ọmọ tí ìwọ bí fúnra rẹ̀ ni yóò jẹ́ àrólé rẹ.” 5Olúwa sì mú Abramu jáde sí ìta ó sì wí fún un pé, “Gbé ojú sókè sí ọ̀run kí o sì ka àwọn ìràwọ̀ bí ó bá ṣe pé ìwọ le è kà wọ́n.” Ó sì wí fun un pé, “Nítorí náà, báyìí ni irú-ọmọ rẹ yóò rí.” 6Abramu gba Olúwa gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.