Native Bible

Genesis 14:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àfonífojì Siddimu sì kún fún kòtò ọ̀dà ilẹ̀, nígbà tí ọba Sodomu àti ọba Gomorra sì sá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà ṣubú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè.

Genesis 14:10 in English

Genesis 14:10 · Berean Standard Bible

Now the Valley of Siddim was full of tar pits, and as the kings of Sodom and Gomorrah fled, some men fell into the pits, but the survivors fled to the hill country.

Context

8Nígbà náà ni ọba Sodomu, ọba Gomorra, ọba Adma, ọba Seboimu àti ọba Bela (èyí ni Soari), kó àwọn ọmọ-ogun wọn, wọ́n sì pa ibùdó ogun wọn sí Àfonífojì Siddimu, 9láti kojú ìjà sí Kedorlaomeri ọba Elamu, Tidali ọba Goyimu, Amrafeli ọba Ṣinari àti Arioku ọba Ellasari (ọba mẹ́rin kọjú ìjà sí ọba márùn-ún). 10Àfonífojì Siddimu sì kún fún kòtò ọ̀dà ilẹ̀, nígbà tí ọba Sodomu àti ọba Gomorra sì sá, díẹ̀ nínú àwọn ọkùnrin ogun náà ṣubú sínú àwọn kòtò náà, àwọn tókù sì sálọ sì orí òkè. 11Àwọn ọba mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà sì kó gbogbo ẹrù Sodomu àti Gomorra àti oúnjẹ wọn; wọ́n sì lọ. 12Wọ́n sì mú Lọti ọmọ arákùnrin Abramu tí ń gbé ní Sodomu àti gbogbo ohun ìní rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.