Gẹnẹsisi 1:9
Genesis 1:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.
Genesis 1:9 in English
Genesis 1:9 · Berean Standard Bible
And God said, “Let the waters under the sky be gathered into one place, so that the dry land may appear.” And it was so.
Context
7Ọlọ́run sì dá òfúrufú láti ya omi tí ó wà ní òkè òfúrufú kúrò lára omi tí ó wà ní orí ilẹ̀. Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 8Ọlọ́run sì pe òfúrufú ní “ọ̀run.” Àṣálẹ́ àti òwúrọ̀ sì jẹ́ ọjọ́ kejì. 9Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí omi abẹ́ ọ̀run wọ́ papọ̀ sí ojú kan, kí ilẹ̀ gbígbẹ sì farahàn.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀. 10Ọlọ́run sì pe ilẹ̀ gbígbẹ náà ní “ilẹ̀,” àti àpapọ̀ omi ní “òkun.” Ọlọ́run sì rí i wí pé ó dára. 11Ọlọ́run sì wí pé, “Jẹ́ kí ilẹ̀ kí ó hu ọ̀gbìn: ewéko ti yóò máa mú èso wá àti igi tí yóò máa so èso ní irú tirẹ̀, tí ó ní irúgbìn nínú.” Ó sì rí bẹ́ẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.