Native Bible

Galatians 4:6 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábbà, Baba.”

Galatians 4:6 in English

Galatians 4:6 · Berean Standard Bible

And because you are sons, God sent the Spirit of His Son into our hearts, crying out, “Abba, Father!”

Context

4Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò kíkún náà dé, Ọlọ́run rán ọmọ rẹ̀ jáde wá, ẹni tí a bí nínú obìnrin tí a bí lábẹ́ òfin. 5Láti ra àwọn tí ń bẹ lábẹ́ òfin padà, kí àwa lè gba ìsọdọmọ. 6Àti nítorí tí ẹ̀yin jẹ́ ọmọ, Ọlọ́run sì ti rán Ẹ̀mí Ọmọ rẹ̀ wá sínú ọkàn yín, tí ń ké pé, “Ábbà, Baba.” 7Nítorí náà ìwọ kì í ṣe ẹrú, bí kò ṣe ọmọ; àti bí ìwọ bá ń ṣe ọmọ, ǹjẹ́ ìwọ di àrólé Ọlọ́run nípasẹ̀ Kristi. 8Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, nígbà tí ẹ̀yin kò tí i mọ Ọlọ́run, ẹ̀yin ti ṣe ẹrú fún àwọn tí kì í ṣe Ọlọ́run nípa ìṣẹ̀dá.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.