Native Bible

Galatians 4:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Abrahamu ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin.

Galatians 4:22 in English

Galatians 4:22 · Berean Standard Bible

For it is written that Abraham had two sons, one by the slave woman and the other by the free woman.*

Context

20Ìbá wù mí láti wà lọ́dọ̀ yín nísinsin yìí, kí èmi sì yí ohùn mi padà nítorí pé mo dààmú nítorí yín. 21Ẹ wí fún mi, ẹ̀yin tí ń fẹ́ wà lábẹ́ òfin, ẹ ko ha gbọ́ òfin ohun ti òfin sọ. 22Nítorí a ti kọ ọ́ pé, Abrahamu ní ọmọ ọkùnrin méjì, ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ ẹrúbìnrin, àti ọ̀kan láti ọ̀dọ̀ òmìnira obìnrin. 23Ṣùgbọ́n a bí èyí tí ṣe ti ẹrúbìnrin nípa ti ara, ṣùgbọ́n èyí ti òmìnira obìnrin ni a bí nípa ìlérí. 24Nǹkan wọ̀nyí jẹ́ àpẹẹrẹ: nítorí pé àwọn obìnrin wọ̀nyí ní májẹ̀mú méjèèjì; ọ̀kan láti orí òkè Sinai wá, tí a bí lóko ẹrú, tí í ṣe Hagari.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.